38°C
May 10, 2024
Yoruba

KÍN NI A FẸ́Ẹ́ MÁA FI ÈDÈ YORÙBÁ ṢE?

  • November 3, 2021
  • 61 min read
  • 361 Views
KÍN NI A FẸ́Ẹ́ MÁA FI ÈDÈ YORÙBÁ ṢE?

By AKÍNWÙMÍ ÌṢỌ̀LÁ

Gíwá Fásitì Adékúnlé Ajáṣin,

Ìgbákejì Gíwá,

Àkọwé Àgbà,

Alákòóso Ètò Ìṣúná Owó,

Alákòóso Ilé-Ìkàwé,

Àwọn Àdíínì àti Adárí Onírúurú Ẹ̀ka,

Òṣìṣẹ́ àti àwọn Akẹ́kọ̀ọ́,

Orí Adé gbogbo,

Gbogbo Ọ̀rẹ́ Fásitì Adékúnlé Ajáṣin,

Ẹ̀yin bàbá àti Ìyá mi,

Àwọn Oníròyìn àti Akàròyìn,

Gbogbo Àlejò tó wà níkàlẹ̀

Ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, lẹ́yìn tí mo di ọ̀jọ̀gbọ́n, mo ní láti ka ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n, wọ́n ní kí n wá ṣe tèmi ní Ẹ̀ka-Ẹ̀kọ́ àwọn Èdè Ilẹ̀ Áfíríkà ní Ilé-Ifẹ̀. Mo wá sọ fún Ọ̀gá Àgbà wa nígbà náà, ẹni tí ó tún jẹ́ ọ̀rẹ́ mi, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wándé Abímbọ́lá pé èdè Yorùbá ló mà yẹ kí n fi ka ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tèmi. Ó ní Yunifásítì kì í mà á ṣe irú rẹ̀ ní èdè Yorùbá! Mo ní ṣebí èdè Yorùbá ni àwa fi ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̣̀ọ́ wa!

         Kí ó tóó di ìgbà náà, a ti jà ìjà pé èdè Yorùbá ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa tí wọ́n bá fẹ́ẹ́ gba àgbàkún oyè bí ọ̀mọ̀wé, yóò máa fi kọ iṣẹ́ wọn.  A gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí ìpàdé Ìgbìmọ̀ àwọn aláṣẹ yunifásítì fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ (Senate) fún àṣàrò. Ẹ̀rín pọ̀ ní ọjọ́ tí a kọ́kọ́ dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. Àwọn kan rẹ́rìn-ín pé, ẹ fẹ́ẹ́ máa fi Yorùbá kọ àbọ̀ ìwádìí ìjìnlẹ̀ fún àgbàkún oyè! Ẹ̀rín tí a ń wí yìí pọ̀. Ṣùgbọ́n nígbẹ̀yìn, wọ́n gbà fún wa o. Ló fi jẹ́ pé títí di òní-olónìí, Yunifásítì Ifẹ̀ àti ti Adékúnlé Ajáṣin, Àkùngbá-Àkókó ni wọ́n ti ń fi Yorùbá kọ àbọ̀ ìwádìí-ìjìnlẹ̀ fún àgbàkún oyè. Ẹ ẹ̀ rí nǹkan! Ẹ jẹ́ mọ̀ pé ní Yunifásítì Ìbàdàn, níbi tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ẹ̀kọ́ Yorùbá pàápàá, wọn ò tí ì máa fi Yorùbá kọ àbọ̀ ìwádìí ìjìnlẹ̀ iṣẹ́ àgbàkún oyè!

         Èyí tí mo kọ́kọ́ ń sọ nípa ìdánilẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n, ẹ jẹ́ mọ̀ pé ibi tí ó parí sí nìyẹn! Wọn ò gbà kí n ṣe é ní Yorùbá. Èmi náà sì kọ̀ láti ṣe é ní èdè Gẹ̀ẹ́sì! Kò má tí ì sí ẹni tí ó tí ì kọ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ iṣẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n tirẹ̀ ní Yorùbá!

Ǹjẹ́ bí ọ̀rọ̀ náà ti rí ní gbogbo orílẹ̀ ayé nìyí? Kí á má tilẹ̀ sọ pé gbogbo ayé, kí a sọ pé ní gbogbo orílẹ̀ tí àwọn amúnisìn ti gba ìjọba rí? Ẹ jẹ́ kí á mú àwọn àpẹẹre mẹ́ta péré gẹ́gẹ́ bí àgbéyẹ̀wò. Ẹ wo ilẹ̀ India, China àti ilẹ̀ Nàìjíríà. Kín ni àwọn ìyàtọ̀? Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni ó gba ìjọba ní India, òun náà ló sì gba ìjọba ní Nàìjíríà. India ti gba òmìnira. Nàìjíríà náà sì ti gba òmìnira. Ṣùgbọ́n ní India lónìí Hindi ni èdè ìjọba, èdè iṣẹ́ àti èdè ẹ̀kọ́! India kò gba àṣà Geẹ̀ẹ́sì, India kò gba ẹ̀sìn Gẹ̀ẹ́sì, India kò gba ẹ̀sìn ọmọlẹ́yìn Kristi! Wọn kì í ṣe onígbàgbọ́. Ẹ̀sìn Hindu ni wọn ń sìn. Wọn kò sọ àṣà wọn nù. Àṣà ṣe pàtakì púpọ̀.

Ẹ tún wo ilẹ̀ China! Ó burú pé lẹ́yìn ọdún tí ó lé ní àádọ́ta tí a ti gba òmìnira, China wa ń fi ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà ṣe ẹrú ní ilẹ̀ Nàìjíríà gan-an nínú ilé-iṣẹ́ tí China kọ́. A kéde ìròyin burúkú yìí nínú ìwé-ìròyìn The Nation ti Sunday; Oct. 20, 2011, p. 23. A ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà tí wọn ń ṣiṣẹ́ ẹrú ní ilé-iṣẹ́ tí China kọ́ sí Nàìjíríà! Wọn máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní aago méje, wọn a sì ṣíwọ́ iṣẹ́ ní aago mẹ́fà alẹ́.

Ẹnì kankan nínú wa kì í ṣe òṣìṣẹ́ gidi. Nígbà tí wọ́n bá ní iṣẹ́ fún wa lásán ni. A le wá lọ́la kí wọn dá wa padà. Iṣẹ́jú mẹ́wàá péré ni a fi ń simi, wọn á sì pàṣẹ pé ká padà sẹ́nu iṣẹ́. Wọn ní ọ̀lẹ ni wá, ohun tí kò jẹ́ kí Nàìjíríà máa ṣe dáadáa nìyẹn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òṣìṣẹ́ lọ́kùnrin ni ìjàǹbá lẹ́nu iṣẹ́ ti sọ di aláàbọ̀ ara láìgba ẹ̀bùn owó kankan. Lọ́sẹ̀ tó kọjá yìí ni ẹ̀rọ iṣẹ́ gé ẹnì kan lọ́wọ́ níbi tó ti fẹ́ẹ́ ṣiṣẹ́. Wọ́n kàn bá a fi òògùn díẹ̀ sí i ni, wọn sì yọ ọ́ níṣẹ́ láìsan owó fún un. Òṣìṣẹ́ obìnrin kan tún fẹjọ́ sùn pé àwọn ọmọ China tó ní iṣẹ́ fẹ́ẹ́ bá òun lòpọ̀. “Bí o bá fẹ́ kí wọn san owó dáadáa fún ọ lóbìnrin, àfi kí wọ́n máa bá ọ sùn.”

         Ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ni China Town, Ọjọ́ta àti ní àwọn ilé iṣẹ́ mìíràn ní Ìlúpéjú nìyẹn níbi tí owó-oṣù ti wà láàrin ₦6,000 àti ₦8,000. Àkọlé àbọ̀ ìwádìí tí a ń wí yìí ni “Bí China ṣe ń gba gbogbo Nàìjìríà”.

         Àpẹẹrẹ kan tí ó dára nípa bí àṣà ṣe máa ń mú ìlọsíwájú bá àwùjọ nìyí. China kò sọ àṣà rẹ̀ nù nítorí èdè Chinese tó jẹ́ èdè wọn ni wọn fi ń kọ́ ọmọ láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ títí dé òpin fáfitì. A ní ìmòye pé ẹ̀kọ́ máa ń yé ọmọ dáadáa nígbà tí a bá fi èdè abínibí rẹ kọ́ ọ. Lílo èdè abínibí ti jẹ́ kí China ní ìlọsíwájú tí ó ga nínú ìmọ̀ sáyẹ́ńsì àti tẹkinọ́lọ́jì. Èyí ni wọn sì ń tà káàkiri ayé báyìí.

         Ṣùgbọ́n èdè àjèjì ni àwa fi ń kọ́ ọmọ láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ dé òpin fáfitì ní orílẹ̀-èdè Nàìj’iríà. Ohun tí ó tún wá ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ ni ti àwọn aṣaájú olóṣèlú wa tí wọn kò ní àǹfààní àtikọ́ ìwà ọmọlúàbí tí ó yẹ kí àṣà ti kọ́ wọn. Wọn kì í ṣolóòótọ́, wọn kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, wọn kò le dáàbò bo ẹ̀tọ́ òṣìṣẹ́ ọmọ-ilẹ̀ wọn ní ìlú tiwọn!

Kín wáá ni àṣà? Àṣà ni àwọn nǹkan ẹ̀mí, àwọn nǹkan àmúlò, ọgbọ́n orí àti ìmọ̀lára tí ó dá àwọn àwùjọ kan yàtọ̀, tí ó fi mọ́ iṣé- ọnà wọn, ìtàn sísọ wọn, bí wọn ṣe gbé ilé ayé wọn, bí wọ́n ṣe ń gbé pọ̀, ìwà tí wọ́n gbà pé ó dára tàbí pé kò dára, ìṣẹ̀ṣe àti ìgbàgbọ́ wọn. [UNESCO, 2002]

Ohun tí ó ṣe pàtàkì káàkiri gbogbo àwọn àwùjọ tó wà ní àgbáyé ni pé wọ́n yàtọ̀ sí ara wọn púpọ̀. Ẹ̀yà kan yàtọ̀ sí èkejì. Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ló sì ní èdè tirẹ̀ láti rí i pé oníkálukú dá dúró gedegbe ni. Nítorí náà, èdè ni ẹ̀mí àṣà. Bí èdè kan bá ti kú, àṣà náà á rọ, á sì kú!

Gbogbo àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ tó ti ṣiṣẹ́ lórí àwọn tó ń sọ èdè Yorùbá ló sọ pé ọ̀làjú ètò-ìṣèlú wọn gbòòrò, ó sì lágbára. Ìmò iṣẹ́-ọnà wọn ga púpọ́, bí a bá rántí àwọn orí-Ifẹ̀ tí wọn fi bàbá ṣe, àti àwọn tí wọn fi òkúta gbẹ́ àti ọgbọ́n àmúṣe tí wọn fi ṣe ẹyọ ìlù dùndún kan ṣoṣo tó ń sọ̀rọ̀ Wọ́n tún sọ nípa ẹ̀sìn tí kì í ṣalátakò, elérò ìjìnlẹ̀, tí ó ní odù ọ̀tálénígba-ó-dín-mẹ́rin (256). Ṣùgbọ́n, èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni ìwà òtítọ́ sísọ tí a fi ń kọ́ ọmọ láti kékeré láti mọ ohun tí ó dára yàtọ̀ sí èyí tí kò dára, láti jẹ́ ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kèlé, láti jẹ ẹni tí ó mọ ohun tí ó tọ́ yàtọ̀ sí èyí tí kò tọ́. Gbogbo ìwọ̀nyí ni ó fún ọmọ Yorùbá ni agbára ìwà tí kò ṣe é dàrú. Èyí ni òṣùwọ̀n ọmọlúàbí. Ṣùgbọ́n o, ìyà tí ó lágbára wà fún aláìgbọràn.

         Ní àwùjọ Yorùbá, bí ọmọ tó gbọ́ràn ṣe wà, bẹ́ẹ̀ náà ni èyí tí kò gbọ́ràn wà. Àwọn ni wọ́n máa ń di àgbà-ìyà. Àwùjọ a sì máa fi ìyà jẹ wọ́n, àwùjọ a máa dójú tì wọ́n, ìtìjú a máa lé wọn jáde ní ìlú.

                  “Kín lẸdún gbé?

                  Owó, owó lẸdún gbé

                  Kín ló fi ṣe?

                  Aṣọ, aṣọ, ló fi rà

                  Aṣọ kín yẹn wà     

                  Gẹgẹ, gẹgẹ òyìnbó.

                  Ẹdún jalè!

                  Ẹdún jalè, ó fòru lọ.

Òṣùwọ̀n ọmọlúàbí yìí ni ogún ńlá tí àtìrandíran ọmọ Yorùbá jẹ, ó sì yẹ kí a máa fi le àwọn ọmọ wa lọ́wọ́, kí gbogbo ayé le jẹ ogún rere náà.

         Jíjà fún ẹ̀tọ́ ẹni yìí ti bẹ̀rẹ̀ ti pẹ́ láti àkókò ètò ìjọba amúnisìn Gẹ̀ẹ́sì ni, nígbà tí àwọn òyìnbó bẹ̀rẹ̀ sí í dẹ́yẹ sí àwọn ènìyàn dúdú. Àwọn ènìyàn dúdú wáá ríi pé ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ tí àwọn òyìnbó mú wá kì í ṣe ti inú bíbélì, ti àpo ara wọn ni. Àwọn alákọ̀wé èniyàn dúdú náà wáá bẹ̀rẹ̀ sí jà fún ẹ̀tọ́ tiwọn, ẹ̀tọ́ àṣà àwọn ènìyàn dúdú. Èyí ni yóò dá iyì tiwọn padà, iyì tí àwọn òyìnbó ti fi dù wọ́n. Láti 1890, wọ́n ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ nípa ìtàn ilẹ̀ Yorùbá àti àwọn àṣà Yorùbá. Ọ̀kan nínú àbọ̀ ìwádìí wọ̀nyí ni ìwé ńlá ìtàn Yorùbá, History of the Yorubas (1921) tí Samuel Johnson kọ. Àwọn ènìyàn ńláńlá mìíràn bínú fi orúkọ òyìnbó tí wọn ti ń jẹ́ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀: David B. Vincent di Mọ́jọlà Agbébí, Rev. J.H. Samuel di Adegboyega Ẹdun. Àwọn mìíràn tún yí orúkọ wọn padà.

         Ohun tí mo ń sọ ni pé nígbàkúgbà ni àtijọ́, nígbà tí wọn bá fẹ́ẹ́ fi àṣà wa àti iyì wa wọ́lẹ̀, àwọn kan, tàbí ẹnì kan a sì dìde láti gbìjà.

         Ṣẹ́ ẹ rántí Herbert Macaulay (1864 – 1946) “baba àgbà ńlá olùfẹ́ ilẹ̀ Nàìjíríà” ẹni tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìjà láti bá òyìnbó jà ní Nàìjíríà. Ó sì tún jà pé wọ́n níláti ṣe ẹ̀tọ́ nípa Eleko Èṣúgbàyí ọba Èko, ó sì rí i pé wọ́n gbà á gẹ́gẹ́ bí ọba Èkó gan-an. Ó sì tún dá Ẹgbẹ́ òṣèlú àkọ́kọ́ sílẹ̀ ní Nàìjíríà “The National Democratic Party” nígbà tí àwọn ènìyàn dúdú gbà pé òyìnbó lọ̀gá.

Herbert Macaulay ní ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ nínú ìgbà àtijọ́ ilẹ̀ Áfíríkà àti àṣà, ó sì rí i pé àṣà àti ìṣe ilẹ̀ Áfíríkà ní àwọn ìwà rere tí a kò rí irú rẹ̀ rí, bí wọn tilẹ̀ yàtọ̀ sí ti àwọn ilẹ̀ míràn, wọn kò kéré ní dídára sí wọn… ó wọ inú awo Ifá, ó sì súnmọ́ Ìjọ Ọ̀rúnmìlà dáadáa… bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò kúrò nínú ìjọ Anglican títí ó fi kú, síbẹ̀síbẹ̀, ó dùn ún pé ìjọ Ọlọ́run ti ba “gbogbo àṣà wa jẹ́” ó sì sọ pé “ojú tí ẹ̀sìn fi ń wo ayé gbọdọ̀ fẹ̀ tó láti gba àwọn ìṣe ilẹ̀ Áfíríkà, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ níí rí ìpìlẹ̀ tí ó lágbára tó láti dúró lé lórí.  (Olusanya nínú Afúyẹ́, 281)

Níbi tí a dé yìí a níláti rántí gbogbo iṣẹ́ tí Awólọ́wọ̀ ṣe. Ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ wọ́n sì dá Ẹgbẹ́ Ọmọ Odùduwà sílẹ̀ láti dáàbò bo ìfẹ́ òṣèlú àti láti gbé àjogúnbá àṣà ga ní ọdún 1945. Nígbà tí ó sì di 1957 ó dá Action Groupsílẹ̀. Ó sì sọ aṣọ Yorùbá àkànpọ̀ onípele mẹ́ta di gbajúmọ̀.

         Ṣùgbọ́n, bí a bá ní kí á wo akitiyan onítara tí ò tètè ṣiṣẹ́ jùlọ lọ́dọ̀ àwọn alágbára ìjọba, èyí tí gbajúmọ̀ Tai Ṣólàárín ṣe nípa ohun tí kò bójú mu kan. Ní àwọn ọdún tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 1970, ojú ọ̀nà ni wọn máa ń fi òkú ènìyàn sí tí yóó fi rà. Díẹ̀díẹ̀ ọ̀rọ̀ náà kò ta àwọn ènìyàn lára mọ́. Ṣólàárín wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn òkú náà sínú pósí, ó sì ń gbé wọn lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé àwọn oníjọba tí ó bá wà ní àdúgbò ibẹ̀. Ó wá jẹ́ kí àwọn ènìyàn tún máa kíyèsí ohun tí kò bójú mu náà. A lè máa ka oríṣiríṣi ohun tí àwọn onígbèjà ti ṣe láti dáàbò bo ìtàn àti àṣà wa. Ohun tí ó ba ni nínú jẹ́ ni pé bí àṣà wa ṣe ń dòfo lọ, tí ìwà ọmọlúàbí wa sì ti bàjẹ́ tán kò dàbí ẹni pé ó ń bí wa nínú.

LÓDE-ÒNÍ

         Ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, ìyẹn ní ọdún 2011, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Ṣóyínká ń sọ̀rọ̀ nípa Àṣà wa tí wọn ti gbógun tì, Culture Under Siege, (The Nation Jan. 1) Ó ń káàánú nípa àìsí ìfaradà nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tí o sọ pé ó ń rà bàbà lórí wa, tí kò sì jẹ́ kí a lè dákẹ́ jẹ́ẹ́ lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún tí ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ ti wọnú ìgbésí ayé àwọn tí òyìnbó ń jọba lé lórí nílẹ̀ Afíríkà. Ogun ńlá tí ó tako àṣà àjogúnbá wa báyìí ni Ìjọ Ẹ̀mí Mímọ́ Tuntun níbi tí ìkórìíra ẹ̀sìn mìíràn pin sí. Kódà nígbà tí wọn bá ń gbàdúrà ní èdè Yorùbá, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọn fi ń ṣe “Amen”. Wọn ń fi tàkúté ìhìnrere-olówó mú àwọn ìjọ wọn lórí rédíò àti móhùn-máwòrán.

To advertise a controversial miracle they blow a thousand trumpets. (Peel 318)

         Wọn gbógun ti gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ àṣà ilẹ̀ Afíríkà, wọn á ní kí àwọn ọmọ ìjọ wọn yí orúkọ wọn padà sí orúkọ ti inú bíbélì, kí wọn sì kọ oríkì wọn! Ó tún burú nísisìnyí ju ti ìgbà Herbert Macaulay lọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn alákọ̀wé Yorùbá kò bá ọmọ wọn sọ Yorùbá mọ́ bẹ́ẹ̀ ni èdè sì ni ẹ̀mí àṣà. A mà ti n sọ ara wa di ìran aláìlédè lọ díẹ̀díẹ̀.

         Àṣà ayélujára ti kó bá bí àwọn obìnrin wa ṣe ń múra. Wọn ń sín àwọn tí wọ́n ń wọ aṣọ kékeré tí kò bo àyà àti itan jẹ, wọ́n sì ń fi irun tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ, olóríṣiríṣi àwọ̀ bo orí wọn. Irun ti wọn rà lọ́jà! Níyì Ọ̀ṣundare pè é ní “ẹwà tí wọn yá lò”; ohun tó pa ni lẹ́rìn-ín níbẹ̀ ni pé àwọn náà á wáá máa ṣe bí àṣà òyìnbó, wọn á máa fi ìka ti gaga irun tó fẹ́ẹ́ dí wọn lójú sẹ́yìn.

KÍN WÁÁ LÓ YẸ KÁ ṢE?

         Gbogbo ohun tí a ti ń sọ bọ̀ fi yé wa pé èdè ni orírun àṣà. Bí a bá ń lo èdè wa ní gbogbo ibi tí ó ti yẹ, ìlọsíwájú wa á dájú. &&&& A gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ láti rí i pé èdè Yorùbá kò kú, iná èdè náà kò sì gbọ́dọ̀ jó àjórẹ̀yìn láwùjọ èdè. Èyí gba ìkíyèsára. Awóbùlúyì (2012) ṣàlàyé pé irúfẹ́ ìkíyèsíra yìí níí ṣe pẹ̀lú gbígbé ìgbésẹ̀ gúnmọ́ láti tako gbogbo ohun yòówù tó lè máa dún kòokò mọ́ ìlò èdè Yorùbá tàbí èyí tó lè fẹ́ dí ìlò èdè bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́.  Adébọ̀wálé (2011) ti tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé àsìkò tó wàyí tó yẹ ká jí gírí sí lílo àti kíkááràmáásìkí èdè Yorùbá nípa fífi kọ́ ọmọ àti nípa sísọ ọ́ k’o má dip é ojú yóò gbà wá tì láwùjọ àgbáyé lẹ́yìnwá ọ̀la.   Awóbùlúyì (2012b) sì wá dábàá pé ọ̀nà kan pàtàkì tí a lè fi dènà ìmúnilẹ́rú èdè lẹ́ẹ̀kejì ni kí a ṣètò bí a ó ṣe máa fi èdè abínibí kọ onírúurú àpìlẹ̀kọ àti iṣẹ́-ọnà. Àlàyé àwọn onímọ̀ wọ̀nyí túbọ̀ fìdí ohun tí mo kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ bá pé ó yẹ kí á máa fi èdè Yorùbá kọ́mọ nítorí pé ohun tí a bá fi èdè abínibí kọ́ni tètè máa ń yéni.

         Yàtọ́ sí èdè tí a mọ̀ mọ́ àṣà, àṣà gan-an ni ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà kó àwọn ènìyàn jọ ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, oníkálukú pẹ̀lú ọgbọ́n inú àti ìmọ̀. Ọlọ́run mọ gbogbo ohun tí ó wà nínú àṣà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀sìn wà láti fi ìdí àṣà, àwọn ìwà ọmọlúàbí múlẹ̀ dáradára. Àṣà ni orísun ìwà rere. Bí àṣà kò bá tí ì kọ́ ọ ní ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin ohun tí ó dára àti èyí tí kò dára, tí o ò bá   di olóòótọ́, ẹni tó ṣe é gbẹ́kèlé, ẹni tí ó ní ìfẹ́, ẹni tó le ṣàlàyé ìnáwó láti inú ẹ̀kọ́ àṣà rẹ, kò níí sí ìpìlẹ̀ tí ó lágbára tí ẹ̀sìn le dúró lé lórí. Bí a bá wò ó dáadáa, ìtumọ̀ kí ènìyàn di àtúnbí ni kí ó padà sí inú àṣà tí Ọlọ́run fún un kí ó lọ kọ́ bí a ti í di ènìyàn rere.

         Bí ọ̀rọ̀ bá dun ènìyàn tó báyìí, tí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ dàbí ẹni pé kò jọ wá lójú mọ́, tí ó dàbí ẹni pé a kò tilẹ̀ dá a mọ̀ mọ́, ohun tí a níláti ṣe ni pé kí á gba ọ̀nà mìíràn wò ó, kí á ta ara wa jí. A kò le jókòó tẹtẹrẹ. Àwa tí a gba iṣẹ́ ìkọ́ni, iṣẹ́ akadá ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga níláti máa tún ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò nígbà gbogbo. Iṣẹ́ àtinúdá, èdè ìperí, àgbéyẹ̀wò ohun tí ó ti wà nílẹ̀.

         Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàyé ní ṣókí ohun tí a ń pè ní àṣà ló wà. Oríṣiríṣi:

  1. “ìrònú ìmọ̀ tí ó ga jùlọ àti àṣeyọrí iṣẹ́ ìdárà” (Prott in Niec 1998: 164)
  2. “Bí a ṣe ń kọ́ni ní àṣà àti orísun tí ó lágbára fún àyípadà, àtinúdá, òmìnira àti àjídìde àǹfààní tuntun” (deCueller J.P. 1995: 19)
  3. “àjọpín ìmọṣẹ́, ìgbàgbọ́ àti àṣà ìbílẹ̀” (Prott in Niec)
  4. “àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀mí, nǹkan ìwúlò, ọ̀rọ̀ òye àti ìmúlára tí ó dá àwùjọ kan tàbí àgbéjọpọ̀ kan yàtọ̀, tí ó kó, dídárà àti àtinúdá ìwé, bí a ṣe é gbélé ayé, ọ̀nà tí a ń gbà gbé papọ̀, ohun tí a gbà pé ó dára, ìṣẹ̀ṣe àti ìgbàgbọ́ (UNESCO, 2002)

Ní gbogbo àjọgbé àti agbo káàkiri ayé, àṣà ni ọ̀nà tí àwùjọ kọ̀ọ̀kan ń gbà jọ gbé pọ̀. Ohun tí ó ṣe pàtàkì jù nípa àṣà ni pé ó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ọ́ nínú Article 1 Unesco Universal Declaration of Cultural Diversity (2001). Oríṣiríṣi àṣà ni àjọni àjogúnbá gbogbo ọmọ ènìyàn. Àṣà pín sí oríṣiríṣi láti ìgbàdégbà àti ilẹ̀ dé ilẹ̀. Oríṣiríṣi tí a ń wí yìí wà nípa dídáyàtọ̀ àti pínpín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ìdánimọ̀ ìsọ̀rí àti I àwùjọ tí ó wà ní àwùjọ ènìyàn. Gẹ́gẹ́ bí orísun ohun tí a ń ṣàjọpín, àtinúdá àti àtinúdá oríṣiríṣi àṣà ṣe dandan fún ẹranko àti igi oko. Bí a bá wò ó báyìí, àjogúnbá gbogbo ẹ̀dá ayé ni, a sì níláti gbà á bẹ́ẹ̀ kí á sì mọ̀ pé fún ire ìran ìwòyí àti ìran tó ń bọ̀ ni.

         Ohun tí a ń sọ ni pé ilẹ̀-ayé le jẹ́ ọ̀kan ṣùgbọ́n ará-ayé kì í ṣe ọ̀kan- oníkálukú agbo ènìyàn ni ó ń ṣẹ̀dá ọ̀nà tí ó fẹjú ọ̀nà àṣà tí wọn ó máa gbà gbépọ̀. Ohun tí a ń sọ ni pé Ọlọrun ti fi hàn pé Òun fẹ́ràn kí nǹkan jẹ́ oríṣiríṣi ní ènìyàn àti ní ẹranko àti igi oko. Ó sì tún dá èdè tí ó dá yàtọ fún àṣà kòọ̀kan láti rí i dájú pé àṣà kọ̀ọ̀kan dá dúró. Bí a bá wò ó báyìí, èdè ni ẹ̀mí àṣà. Bí èdè kan bá kú, àṣà náà á rọ, áá gbẹ, á sì kú. Èdè ni ó wà láàrin gbùngbùn àyíká kẹ̀kẹ́ èdè, àwọn ẹ̀ka àṣà yòókù sì jẹ́ igbo tí ó so àyíká mọ ààrin gbùngbùn tí ó sì máa ń fún un ní àbò tó kún, tó sì lagbara. Ọ̀rọ̀ àwámárìídìí tó so mọ́ ìdásílẹ̀ èdè kò tí ì yé ẹni kankan. Ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn ni pé ẹ̀bùn ńlá tí Ọlọ́run fún ọmọ ènìyàn ni èdè. Àwọn ọ̀rọ̀ àwíṣẹ bí-idán tí ó so mọ́ èdè tún fún ìgbàgbọ́ yìí lágbára. Ọlọ́run nìkan ló le fún ènìyàn ní irú agbára bẹ́ẹ̀. Pẹ̀lú èdè, àwọn ènìyàn àwùjọ kan ni irin-iṣẹ́ fún àtiṣẹ̀dá àti atifìmọ̀ pamọ́ ní ọ̀nà tí ó ṣe é rántí láti ṣe ìpìlẹ̀ fún òdiwọ̀n ìwà ní gbogbo ọ̀nà ilé ayé láti rí i dájú pé ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú wà. Nítorí náà, gbogbo àṣà ni ó ní òfin tí ó sọ ohun tí ó ṣe é ṣe ní gbogbo ìgbà. Ohun tí ó ṣe kókó jùlọ ni ọ̀nà tí a ń gbà tọ́ ọmọ.

         Ó yẹ kí á mọ̀ pé gbogbo èdè ló ní ìtàn ìwáṣẹ̀ ti ènìyàn àti èdè. Èdè bí ẹgbẹ̀rún méje ló wà ní ayé. Kò sí ìtàn ìwáṣẹ̀ kan tí ó le sọ ara rẹ̀ di ìtàn òtítọ́. Bí a bá wò ó báyìí, kò sí ìtàn ìwáṣẹ̀ kan tí ó ga ju òmíràn lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àṣà kan ti polówó ìtàn ìwáṣẹ̀ tiwọn nípa ìpolówó ẹ̀sìn tipátipá, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ sọ ìtàn ìwáṣẹ̀ lásán di òdodo ìtàn gidi ní ọkàn àwọn tí a ń tànjẹ, nípa ẹ̀sìn, tí wọn ti di etí wọn sí àwọn ìtàn àǹfààní láti inú àṣà mìíràn. Etí ènìyàn Ọlọ́run rere láti ṣí sílẹ̀ láti gbọ́ àwọn ìtàn ilẹ̀ mìíràn, ṣùgbọ́n ó níláti dáàbò bo ìtàn àṣà tí Ọlọ́run fún un.

         Kí n má gbàgbé ohun tí mo sọ pé ó yẹ kí á máa fi èdè Yorùbá ṣe ni àwọn ilé ẹkọ́ gíga Yunifásítì. Ẹ tilẹ̀ jẹ́ ká walé. Ní Adékúnlé Ajásin Yunifásítì, Àkùngbá-Àkókó yìí, ní Ọjọ́ Ìṣẹ́gun October 11, 2011, Ọ̀jọ̀gbọ́n Olúyẹ́misí Adébọ̀wálé ka ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì! Ó pe àkọlé rẹ̀ ní Writing and Reacting: The Experience in Indigenous Yoruba Literary Art. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí kún fún gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ nípa ohun tí a ń pè ní iṣẹ́-akadá bíi literary theoryàti criticismtí ó yẹ kí a máa fi èdè Yorùbá kọ. Báwo ni ìbá ti dùn tó bí ó bá jẹ́ pé Yorùbá ni Olúyẹ́misí Adébọ̀wálé fi kọ ọ́! Èmi gbà pé ọwọ́ wa ló kù sí. Bí India, China àti Japan bá ti ń lo èdè tiwọn láti fi wá ìmọ̀, kín ló ń dá àwa náà dúró? Ẹ má ṣì mí gbọ́ o! N ò sọ pé kí a má fọ Gẹ̀ẹ́sì mọ́ o. Dandan ni kí gbogbo wa kọ́ Gẹ̀ẹ́sì, èdè ayé nìyẹn. Èmi náà gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì, kódà mo gbọ́ Faransé, mo sì lè sọ èdè méjèèjì náà dáadáa.. Àwọn ara India, China àti Japan náà gbọ́ gẹ̀ẹ́sì dáadáa, ṣùgbọ́n èdè tiwọn ni wọn fi ń wá ìmọ̀.

         A kò tí ì dáhùn ìbéèrè ìbẹ̀rẹ̀. Kín la fẹ́ máa fi èdè Yorùbá ṣe gan-an? Ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àṣà Yorùbá ni ìwà ọmọlúàbí. Báwo ni a ṣe ń sọ ènìyàn di ọmọlúàbí? Láti kékeré ni. Ó wà lọ́wọ́ ìyá àti bàbá. Wọ́n ní láti kọ́ ọmọ wọn. Gbogbo rẹ̀ sì dálérí àṣà, èdè sì ni orírun àṣà. Nínú èdè ni gbogbo èròjà àṣà wà. Ọ̀kan nínú èròjà àṣà ni ìtàn sísọ: àlọ́ àpamọ̀ àti àlọ́ àpagbè. Àlọ́ ìjàpá àti àwọn àlọ́ mìíràn, àti àwọn ìtàn mìíràn. Bí ilẹ̀ bá ti ṣú, àlọ́ pípa a bẹ̀rẹ̀. Gbogbo ará ilé a tẹ́tí sílẹ̀. Àgbàlagbà á dára yá, ọmọdé a sì kọ́gbọ́n. A kì í gbàgbé àlọ́ bọ̀rọ̀, èròjà ìkọ́nilọ́gbọ́n gidi ni. Ṣùgbọ́n báwo ni èdè tí a fi ń sọ̀rọ̀ gan-an ṣe dé ààrin àwọn ọmọ ènìyàn?

ÌTÀN ÈDÈ

         Nígbà tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá ayé, ayé èrò ọkàn lásán ni. Ọlọ́run dá àwọn òrìṣà-ẹni-àìkú, ó dá àwọn ènìyàn, ó sì dá àwọn ẹranko. Àwọn òrìṣà ni Ọlọ́run kọ́kọ́ rán sọ̀kalẹ̀ wá sí ayé. Bí Ọlọ́run bá fẹ́ẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀, Ọlọ́run lè kàn fi èrò náà sí ọkàn wọn, tàbí kí ó kúkú bá wọn sọ̀rọ̀ tààrà.  Ọlọ́run le bá wọn sọ̀rọ̀, wọn máa gbọ́, yóó sì yé wọn, ṣùgbọ́n àwọn kò le bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ padà. Bí wọ́n bá fẹ́ ohunkóhun, bí wọ́n bá ti fi ọkàn ro èrò náà, yóò ti yé Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò sì fún wọn.

         Ṣùgbọ́n a máa ṣòro púpọ̀ láti bá ara wọn gba èrò papọ̀. Wọn kò le sọ̀rọ̀, wọn kò sì lè mọ ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ń rò ní ọkàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún wọn ní ààyè láti máa fi ọwọ́ júwe tàbí kí wọn máa rẹ́rìn-ín tàbí kí wọn máa rojú.

         Ọlọ́run wáá fún wọn ní ààyè kan sí i. Bí wọn bá fẹ́ fi èrò ọkàn wọn hàn elòmíràn, wọn níláti fi orí wọn kan ti olúwarẹ̀. Bí mo bá fẹ́ẹ́ fi èrò mi kan hàn ọ́, mo níláti fi orí mi kan tìẹ. Ìbáraẹni-sọ̀rọ̀́ wáá di ìforíkorí ìgbà gbogbo. Ibi tí a ti rí ọ̀rọ̀ foríkorí nìyẹn! Ó ṣe é ṣe díẹ̀ láàrin ènìyàn méjì, ṣùgbọ́n bí ọ̀pọ̀ ènìyàn bá fẹ́ẹ́ ṣàṣàrò ọ̀rọ̀ kan, gbogbo rẹ̀ a máa di ìdàrúdàpọ̀. Àwọn ènìyàn bá padà tọ Ọlọ́run láti bẹ̀bẹ̀ pé kí àwọn náà le máa sọ̀rọ̀ láàrin ara àwọn, kí àwọn sì le máa bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, kí ayé le rọ̀ wọ́n lọ́rùn. Nítorí náà, kí àwọn ènìyàn lè máa gbọ́rọ̀, kí wọ́n sì le máa sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sọ pé Òun níláti fọ etí wọn, kí òun sì fi ọwọ́ kan ahọ́n wọn. Ọlọ́run pe gbogbo wọn láti ayé wá sí iwájú Rẹ̀ níbi tí ó ti fọ etí gbogbo wọn, tí ó sì fọwọ́ kan ahọ́n wọn. Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ràn, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀!

         Kíá ní òrìṣà Ifá ti di aṣiwájú fún wọn nítorí pé ó tètè ní ìmọ̀ ju àwọn yòókù lọ. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní “Akéré fínú ṣọgbọ́n”. Síbẹ̀ wàhálà ọ̀rọ̀ sísọ ènìyàn kò tí ì parí o, nítorí pé wọ́n rí i pé àwọn ọmọ tuntun wọn náà kò le sọ̀rọ̀. Àwọn ọmọ ń dàgbà, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀. Ó di pé wọ́n níláti máa gbé àwọn ọmọ náà lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kí ó le máa fọ etí wọn, kí ó sì máa fi agbára sí ahọ́n wọn. Ó dàbí ẹni pé gbogbo ìgbà tí wọn bá ti bímọ ni wọn níláti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Iṣẹ́ ńlá ni.

         Wọ́n tún níláti padà lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, wọ́n bẹ̀ Ẹ́ kí ó da ọ̀rọ̀ wọn rò. Ọlọ́run ronú lórí ọ̀rọ̀ náà títí, ó sì wá ọ̀nà láti parí ìṣòro náà títí ayé. Ọlọ́run yóò fi ètò etí fífọ́ náà àti ahọ́n fífún-lágbára sí ara ètò ọ̀nà ìbímọ, tí ó fi jẹ́ pé etí ọmọ yóò ti jẹ́ fífọ̀, tí ahọ́n yóò sì ti lágbára bí a bá ti ń bí wọn.

         Ọlọ́run wá rò pé ara ẹni kan ṣoṣo ni Òun ó fi agbára náà sí. Òun le fi ètò náà sí ara ọkùnrin nípa oje ara rẹ̀ tàbí sára obìnrin sínú ilé-ọmọ rẹ̀. Kí Ọlọ́run tó mú ọ̀kan, ó pe ọkùnrin kan àti obìnrin kan, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́tọ́ọ̀tọ̀. Ó bi oníkálukú pé kín ni wọn fẹ́ fi ọmọ ṣe. Kíá ni ọkùnrin dáhùn pé òun ń fẹ́ ẹni tí òun yóò máa rán níṣẹ́ tí yóò sì máa bá òun ṣiṣẹ́ lóko. Èsì tí obìnrin fọ̀ kún fọ́fọ́. Obìnrin fẹ́ràn ọmọ fún oríṣiríṣi ìdí. Ó fẹ́ẹ́ máa tọ́ wọn dàgbà, ó fẹ́ẹ́ máa wẹ̀ wọ́n kí ó máa fún wọn lóúnjẹ, kí ó sì máa gbé wọn pọ̀n, ó fẹ́ẹ́ máa bá wọn ṣeré, ó fẹ́ẹ́ máa bá wọn sọ̀rọ̀, kí wọn jọ máa kọrin! Ó wáá rán Ọlọ́run léti pé òun mà ti ń gbé ọmọ sí ikùn òun fún odidi oṣù mẹ́sàn-án! Ọlọ́run rẹ́rìn-ín múṣẹ́. Ó hàn gbangba pé ara obìnrin ló bá irú iṣẹ́ náà mu.

         Ọlọ́run wáá pinnu láti fi agbára láti fọ etí àti láti ró ahọ́n lágbára náà sí ilé-ọmọ obìnin, gbogbo ètò náà yóò sì ti parí bí a bá ti n bí ọmọ. Ọmọ náà yóò le tètè máa kọ́ èdè bí o bá ti ń dàgbà. Bí ó sì ti rí nìyẹn láti ìgbà náà. Èyí ló fà á tí obìnrin fi ṣe pàtàkì nípa èdè sísọ. Àwa Yorùbá a ní “bí ọmọ ó la-ohùn, igbe “baba! níí kọ́kọ́ ké”. Ṣùgbọ́n àwọn Gẹ̀ẹ́sì ń pe èdè àkọ́sọ ní èdè ìyá (mother tongue!) Ọ̀rọ̀ pọ̀ níbẹ̀!

         Bí èdè ṣe dé ilé ayé nìyẹn o. Èdè sì yàtọ̀ láti ilẹ̀ dé ilẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni àṣà ṣe yàtọ̀.

ÌTÀN KEJÌ TÍ MO FẸ́Ẹ́ SỌ NI EWÚRẸ́ ÀTI Ọ̀BỌ

         Ewúrẹ́ àti Ọ̀bọ bẹ̀rẹ̀ síí jiyàn níwájú ààfin ọba. Iyàn jíjà náà lágbára púpọ̀. Ọ̀bọ sọ pé òun bímọ púpọ̀ ju ewúrẹ́ lọ. Ewúrẹ́ náà sì ni òun bímọ púpọ̀ ju ọ̀bọ lọ. Ariwo yìí ń ta ọba léti, ọba si pàṣẹ pé kí àwọn akọ́dà lọ kó àwọn aláriwo náà wá sí iwájú òun. Nígbà tí wọn ro ẹjọ́ wọn, ọba fi wọn rẹ́rìn-ín, ọba ní “ẹ̀yin mà gọ̀ púpọ̀ o! Ẹ̀yin ń jiyàn lórí ohun tí kò le rújú rárá bí ó bá jẹ́ pé ọlọ́gbọ́n ni yín ṣebí ọ̀rọ̀ ọmọ lẹ ń sọ? Ọmọ ṣe é kà! Bí ó bá di àárọ̀ kùtù ọ̀la, kí oníkálùkù yín máa kó ọmọ tirẹ̀ bọ̀ wá sí iwájú ààfin mi níbi. A ó ka iye ọmọ tí oníkálukú bí, a ó sì le sọ ọmọ ẹni tí ó pọ̀ jù”.

         Òkìkí ti kàn káàkiri ìlú pé ewúrẹ́ àti ọ̀bọ ń kó ọmọ wọn bọ̀ wá sí ilé ọba láàárọ́ ọ̀la láti wáá kà wọ́n. Kí ilẹ̀ tóó mọ́, èrò ńlá ti pé láti wáá wòran.

         Ewúrẹ́ ló kọ́kọ́ dé, ó sì kó gbogbo ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn. Kò kúkú bí ju ọmọ mẹ́rin náà lọ, ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀, òbúkọ náà tẹ̀lé e. Nígbà tí ọ̀bọ kó àwọn ọmọ tiẹ̀ bíi mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n dé, gbogbo ayé ti gbà pé ewúrẹ́ ti jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.

         Nígbà ti ọba jáde sí ìta, ó jókòó sórí àga gíga rẹ̀ ńlá kan, ó sì ké sí àwọn tó ń jiyàn náà, kí wọn kó ọmọ wọn jáde, kí wọn ó le kà wọ́n.

         Ewúrẹ́ ló kọ́kọ́ jáde, ó kí ọba, ó sì ní kí ọba jẹ́ kí òun kọ́kọ́ fi ara òun àti ọkọ òun han ọba ná. Ọba ní kò burú.

         Ewúrẹ́ ní: “Ọkọ mi nìyí o. Ọ̀gbẹ́ni Òbúkọ.” Òbúkọ yára dọ̀bálẹ̀, ó kí ọba. Gbogbo wọn pàtẹ́wọ́ wọ́n kí Òbúkọ.

         Èmi sì nìyí Ìyáàfin Àkẹ̀, èmi ni ìyá gbogbo àwọn ọmọ wọ̀nyí. Ó kúnlẹ̀, ó kí ọba, gbogbo ayé sì patẹ́wọ́.

         Kí n tóó máa bá ọ̀rọ̀ lọ, ó yẹ kí n ṣàlàyé pé Àkẹ̀ ni a máa ń pe àwọn ewúrẹ́ tó bá tóbi jùlọ, irú èyí tí àwọn babaláwo ńlá fẹ́ràn láti máa fi ṣe ẹbọ. Irú babaláwo bẹ́ẹ̀ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewúrẹ́ bẹ́ẹ̀ lágbàlá, tàbí lẹ́kùlé, tí wọn so mọ́lẹ̀, mọ́ èèkàn tàbí igi. Yóò sì máa já okùn èyí tó bá fẹ́ẹ́ fi ṣe ẹbọ nígbàkígbà. Irú àwọn babaláwo báwọ̀nyí ni wọ́n máa ń fún ní oríkì “ọ̀jákẹ̀nídèfiṣẹbọ” ẹni tí ó já Yorùbá ní ìdè (lórí ìso) láti fi ṣe ẹbọ, tàbí kí á kàn wí pé Jákẹ̀nídè. Ibẹ̀ ni orúkọ Jákànńdè ti wá.

         Ewúrẹ́ wá rọra ń fi àwọn ọmọ rẹ̀ han ọba. “Ọmọ mi àkọ́bí nìyí Ọ̀gbẹ́ni Láyẹ̀wú. Láyẹ̀wú kí ọba dáadáa, wọ́n sì pàtẹ́wọ́, ọmọ mi kejì rè é Arábìnrin Ìdérègbè, ó kúnlẹ̀, wọ́n sì pàtẹ́wọ́. Ọmọ mi kẹta nìyí Arábìnrin Asinrin, ó kí ọba, wọ́n sì pàtẹ́wọ́. Tóò, kí àwọn yòókù tóó dé ẹ jẹ́ kí n fi ọmọ mi kékeré hàn yín o, òun ni Láróńdó. Láróńdó fò sókè lẹ́ẹ̀mẹta, ó kí ọba, ariwo sì ta, wọ́n kí Láróńdó.

         Ewúrẹ́ ni òun fẹ́ fún Ọ̀bọ náà láyè kò fi àwọn ọmọ tirẹ̀ náà han ọba. Ọba ní kò burú.

         Ọ̀bọ kí ọba, o ní èmi ni Ìyáàfin Ọ̀bọ, ọkọ mi sì nìyí Ọ̀gbẹ́ni Ọ̀bọ. Àwọn ẹranko pàtẹ́wọ́.

         Ó tẹ̀ síwájú “ọmọ mi àkọ́bí nìyí” “Ọ̀gbẹ́ni Ọ̀bọ, èkejì nìyí Ọ̀gbẹ́ni Ọ̀bọ, ẹ̀kẹta sì nìyí Arábìnrin Ọ̀bọ, ẹ̀kẹrin náà sì nìyí Ọ̀gbẹ́ni Ọ̀bọ.

         Ọba sì bẹ̀rẹ̀ síi rẹ́rìn-ín. Ó ní Ọ̀bọ ni gbogbo yín. Kò sí ìyàtọ̀ láàrin yín. Bí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún, ọ̀bọ náà ni yín. A dá àwọn ewúrẹ́ mọ̀ tọkọ, taya tọmọ. Ọba sọ pé òun gbà pé ewúrẹ́ ló jàre ọ̀rọ̀ náà. Ó ní ọkọ, ó sì ní ọmọ. Orúkọ ń ro ni. Orúkọ sì ní ìtumọ̀. Báwo ni a ó ṣe dá Yorùbá mọ̀?

         Ẹ ò ráyé lóde! Ó dọwọ́ wa o.

Ìtàn ni n ó fọjọ́ oní sọ! Orin mi dọ̀la. Ẹ máa wo ìwà àwà ènìyàn láwùjọ ẹyẹ àti ẹranko! Ìtàn ẹyẹ méjì nìyí o, Ṣọ́ṣọ́ àti Ṣákùrọ́ tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ṣọ́ṣọ́ mọ orin ín kọ púpọ̀, ó sì dàbí ọlọ́pàá tó máa ń mú àwọn aṣebi nínú igbó. Ó máa ń kọ orin dídùn láti bú àwọn ẹyẹ ńlá tó bá hùwà ìbàjẹ́. Orin dídùn wọ̀nyí á gba igbo kan, ojú á sì máa ti àwọn aṣebi náà. Ẹ̀rù Ṣọ́ṣọ́ á sì máa bà wọ́n. Níbi tí ẹ̀rù bíbà bá sì ti wà, ìkórìíra náà níláti wà.

         Ẹ jẹ́ ká fi ìtàn kékeré kan ṣàlàyé iṣẹ́ tí orin Ṣọ́ṣọ́ yìí máa ń ṣe láwùjọ ẹyẹ. Àwọn ẹyẹ tó kéré jùlọ méjì kan ń ṣe ọ̀rẹ́. Èkínní a máa jẹ́ Ìròrẹ́, èkejì a sì máa jẹ́ Olongo. Lásán lolongo ń fẹnu bá wọn jẹ́ẹyẹ. Ọ̀rẹ́ àwọn ẹyẹ méjì yí pọ̀ gan an.

         Ní ọjọ́ kan Ìròrẹ́ ní láti lọ sí ìrìnàjò kan tí ó jìnnà, tí ó sì léwu. Ó sì rò pé ìyàwó òun, tí ó jẹ́ ọmọdé, kò níí le bá òun lọ. Ó pinnu láti fi ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ Olongo títí òun ó fi tàjò dé, Olongo fi tayọ̀tayọ̀ gba ìyàwó ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ́dọ̀. Ó kàn jẹ́ pé wàhálà kan wà nípa ètò yí ni. Ìyàwó Ìrorẹ́, ọ̀rẹ́ Olongo tí a ń wí yìí ti dára, ó lẹ́wà púpọ̀ jù! Ojú kò ṣe é mú kúrò lára rẹ̀. Láìpẹ́ Olongo di olùfẹ́ ìyàwó Ìrorẹ́, ọ̀rẹ́ rẹ̀! kò ṣe é gbọ́. Wọ́n ṣe ohun tí kò yẹ kí wọ́n ó ṣe. Wọ́n súnmọ́ ara wọn. Kò ṣe é gbọ́! Àṣírí tú, nítorí pé ìyàwó Ìrorẹ́ lóyún. Èèmọ̀! kí wọn ó tóó mọ ohun tí wọ́n le ṣe, Ìrorẹ́ tàjò dé! Olongo yára sáré gba ọ̀nà ẹ̀bùrú jáde. Ojútì kò jẹ́ kí ìyàwó Ìrorẹ́ le sọ̀rọ̀. Ìrorẹ́ yára sáre lọ fi ẹjọ́ náà sun ọba. Ẹni tí ó bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀, pípa ni tàbí lílé lọ kúrò nílùú. Ọba ránṣẹ́ pe Olongo kí ó wá wí ti ẹnu rẹ̀. Olongo mọ̀ pé òun jẹ̀bí ọ̀rọ̀ náà, ó rọra dọ́gbọ́n, ó ń ṣe bíi wèrè níwájú ọba. Kò pẹ́ tí àánú rẹ̀ fi ń ṣe àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọba ti bẹ̀rẹ̀ síí rò pé orí Olongo ti dàrú, ó sì fẹ́ẹ́ forí jìn ín, Ṣùgbọ́n kí ọba tóó sọ̀rọ̀, Ṣọ́ṣọ́, olóhùn arò ti yára gbé orin kan:

                  Kó o tó sínwín Olongo

                  Olongo sínwín

                  O ó tànràn èyí ná o

                  Sínwín Olongo

                  Olongo sínwín.

Kíá, ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ wá hàn sí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́kàn, wọ́n sì rí i pé Olongo ń díbọ́n ni! Ọba náà rí i, ó sì pàṣẹ kí wọ́n lé Olongo lọ nílùú.

         Ẹ kò rí irú iṣẹ́ ńlá ti orin Ṣọ́ṣọ́ máa ń ṣe láàrin àwọn ẹyẹ. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀ta Ṣọ́ṣọ́ pọ̀. Ṣákùrọ́ ní ọ̀rẹ́ kan náà tí ó ni.

         Ní ọjọ́ kan, ọ̀fọ̀ ńlá ṣe Ṣọ́ṣọ́, ìyàwó rẹ̀ ṣe aláìsí. Ó kú. Ìbànújẹ́ dé bá a. Gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn, ẹni tí aya rẹ̀ bá kú gbọ́dọ̀ dúró sí inú ilé, kò gbọdọ̀ jáde kúrò lọ sí ibi kankan, kò ráyè wá oúnjẹ kankan jẹ. Ebi ti ń pa á púpọ̀. Gbogbo ẹyẹ inú igbó wá ń kí i kú ìrọ́jú. Wọ́n ní kí ó mọ́kàn, kí ó fọ̀rọ̀ mọ́ Ọlọ́run. Wọ́n sì tún ń wá lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀. Ẹlòmíràn ń wá àwatúnwá! Ebi wá ń pa Ṣọ́ṣọ́ gan-an báyìí. Kò lágbára mọ́. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Wọ́n tún ń wá! Ṣé wọ́n mọ̀ pé ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú ṣá? Wọ́n mọ̀. Wọ́n fẹ́ kó kú ni. Kí ọ̀tá wọn olórin kúkú kú, kí ohun tí ó ń rùn tán nílẹ̀. Nígbẹ̀yìn Ṣákùrọ́, ọ̀rẹ́ Ṣọ́ṣọ́ gidi tí ó ti lọ sí àjò tipẹ́ padà dé! Ó sáré lọ kí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Ṣọ́ṣọ́ tí ọ̀fọ̀ ṣè. Ẹ̀rù bà á nígbà tí ó rí i pé ọ̀rẹ́ òun ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Ó mọ ohun tí ó fà á. Ó sáré lọ sí inú oko ata kan. Ata ni ààyò oúnjẹ Ṣọ́ṣọ́. ó re ata, ó dì í sínú ewé ńlá kan, ó sì bu omi lọ́wọ́. Bí ó ti padà wọlé, ó pe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sínú yàrá, ó sì gbé oúnjẹ rẹ̀ fún un. Ṣọ́ṣọ́ ń sáré jẹun, ó sì mu omi lé e. Bí ó ti ń mu omi, ó ń na ọrùn rẹ̀ sókè, sí ọ̀run, ó fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ọba òkè. Kò pẹ́ púpọ̀ mọ́ tí ara Ṣọ́ṣọ́ fi le. Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin. Ẹ kò rí iṣẹ́ Ṣákùrọ́, ọ̀rẹ́ tòótọ́! Níbo ni àwọn Ṣákùrọ́ èdè wa tó ń kú lọ yóò ti wá?

ÌYÁ EHORO

         Ìyá Ehoro ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ tuntun ni, gbogbo àwọn ẹranko igbó sì lọ kí i kú ewu. Àkókò yìí ṣe pàtàkì fún ìyá Ehoro nítorí pé gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán tẹ́lẹ̀. Ó se oúnjẹ púpọ̀, àwọn ẹranko  sì ń jẹ, wọn ń mu. Ṣùgbọ́n kinní kan ń bà wọ́n lẹ́rù. Bí wọ́n bá ti wọlé, tí wọ́n sì kí ìyá ọmọ tuntun, kì í dá wọn lóhùn, ojú ló máa ń mọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn.

         Wọ́n wáá pinnu láti gba àdúrà àgbàpọ̀. Wọ́n ní kí Túùpú Ẹlẹ́dẹ̀ Ẹgàn ṣaájú wọn nínú àdúrà. Túùpú ní kí gbogbo ẹranko máa wí tẹ̀lé òun bí òun bá ti ń gbàdúrà, kí wọ́n sì máa ṣe àmín. Túùpú bẹ̀rẹ̀, ó ní “Kí Olódùmarè, ọba àánú, olùṣọ́ ẹranko àti ẹyẹ nínú igbó dákun máa dáàbo tí ó lágbára bo Ìyá Ehoro àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní àkókò yí tí ó kún fún ewu. Àmín.  Àwọn yòókù náà ń ṣe Àmín tẹ̀lé Túùpú. Wọ́n gbàdúrà títí. Ṣùgbọ́n Túùpú Ẹlẹ́dẹ̀ Ẹgàn ṣàkíyèsí pé Ìyá Ehoro kò bá wọn gbàdúrà, kò sì ṣe Àmín kankan. Ṣé ẹ mọ̀ pé bí àwọn ẹranko bá ń gbàdúrà, àwọn kì í dijú. Ó léwu! Túùpú dá àdúrà dúró. Ó wáá bi Ìyá Ehoro pé kín lódé tí kò fi bá wọn gbàdúrà, tí kò sì ṣàmí àdúrà, ṣebí òun ló bímọ? Ìyá Ehoro mọ́ gbogbo wọn lójú tákí, inú bí i, ó ní “Ẹ̀yin alágàbàgebè gbogbo wọ̀nyí. Ẹ róòótọ́ nílẹ̀ ẹ ẹ̀ le sọ! Ṣé àdúrà òtítọ́ ni ẹ ń gbà yẹn? Taa lẹ ń gbàdúrà sí?” Gbogbo wọn dákẹ́ lọ gbáà. Ẹnu yà wọ́n! Ẹfọ̀n ní àdúrà gidi ni a ń gbà, Olódùmarè ni a sì ígbàdúrà sí.

         Ìyá Ehoro dáhùn, ó ní “Ṣebí ẹ mọ̀ pé Olódùmarè ló fún mi lọ́mọ, ẹ sì mọ̀ pé rere ni Ọlọ́run, kì í ṣe ibi. Kò níí fún ẹranko lọ́mọ tán kí ó tún máa pa á.” Àwọn ẹranko ní lóòótọ́ ni. Ìyá Ehoro wáá ké mọ́ wọn, ó ní “Ẹ ń kanrí mọ́lẹ̀, ẹ ń gbọnra pìtìpìtì, ṣebí ẹ mọ ẹni tó ń pa yín lọ́mọ, à bí ẹ ẹ̀ mọ̀ ọ́n? Ọdẹgbárò, ọmọ Ògúndélé ni kí ẹ lọọ bẹ̀, kò yé fi ìbọn rẹ̀ pa yín lọ́mọ mọ́ o.

         Àwa náà níláti wá àwọn Ògúndélé ilé ayé tí wọ́n fẹ́ẹ́ pa àṣà wa run. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré o. A kò le jókòó tẹtẹrẹ kí àwọn ọmọ wa sì sọ Yorùbá tì! Àṣà yàtọ̀ sí ẹ̀sìn o. Ó le jẹ́ mùsùlùmí gidi, kí o sì jẹ́ ọmọ Yorùbá rere. O le jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kírísítì kí ó sì máa sọ Yorùbá tó dára. Ọlọ́run ló fún wa ní àṣà tiwa o. A kì í ṣe ọmọ burúkú o. Ẹ̀yin olóṣèlú wa ẹ múra sí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá o. Dandan ni o.

         Ká tóó parí ọ̀rọ̀ yìí, ó ku ìtàn kan fún ẹ̀yin àgbà àti ẹ̀yin aṣaájú olóṣèlú ilẹ̀ Yorùbá. Ó dọwọ́ yín o!

         Ṣebí ẹ mọ ẹyẹ Àwòko? Àwòko, ọ̀gá èdè! Àwòko gbọ́n, ó gbédè, ohùn rẹ̀ sì dùn. Bí Àwòko bá ń súfèé kọrin lóko, ẹ ẹ́ ṣebí ènìyàn ni. Àwọn kan tí ò mọ̀ máa ń sọ pé odídẹrẹ́ lọ̀gá èdè, Irọ́ ni. Odídẹrẹ́ kàn máa ń sín ènìyàn jẹ ni. “Èyí tí a bá ti wí, abẹnu gbáro bí òkòtó òkun”. Àwòko máa ń sọ ọ̀rọ̀ tirẹ̀ ni. Àwọn àgbẹ̀ máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àti orin Àwòko lóko. Àwòko a máa kọ orin ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọdé ẹyẹ nínú igbó, ohùn rẹ̀ a sì máa dùn. A máa fi orin sọ pé “Bá a bá débi tí ò jọ tàná mọ́, a kì í dúró jẹun” Ṣùgbọ́n àwọn ọmọde ẹyẹ bí Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ kì í fetí sí àwọn ìkìlọ̀ orin bẹ́ẹ̀.

         Ní ọjọ́ kan ebi ń pa Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀, ó sì wa oúnjẹ lọ. Ó dé ibì kan, ó sì rí i pé ibẹ̀ ṣe bí ẹni tó yàtọ̀ díẹ̀. Wọ́n tó àwọn igi kan jọ bákan ṣá. Olóko ti dẹ okùn fún ẹyẹ, ó sì fi oúnjẹ ẹyẹ síbẹ̀. Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ rántí orin Àwòko, ṣùgbọ́n ebi ń pa á gan an ni. O rò ó títí, ó wáá fọkàn ara rẹ̀ balẹ̀, ó ní “Ìyàtọ̀ èyí ò tíì pọ̀jù, kò leè séwu, kò le séwu. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun. Kíá náà ni okùn gbé Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀! Bí í ti ń jà pìtìpìtì ni okùn ń fún un lọ́rùn!

         Àwòko, àgbà ẹyẹ, ọ̀gá èdè rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀, ó sì mọ̀ pé yóò kú tó bá pẹ́. Ṣùgbọ́n kò sí ohun tí Àwòko lè ṣe àfi bí olóko tó dẹ okùn náà bá wáá tú okùn lọ́run Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀! Bí olóko bá fi dé bá Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀, pípa ni yóò pa á. Àwòko ronú ohun tí ó lè ṣe.  Gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá èdè, Àwòko wá ibi tí olóko wà, ó fò lọ sí orí igi kan nítòsí ibẹ̀, ó wá ń fi orin sọ fún olóko pé:

                  Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ tokùn bọrùn,

                  Ó sọ dùgbẹ̀-dùgbẹ̀,

                  Olókùn wá wo okùn rẹ!

                  Olókùn wá wo okùn rẹ!

         Ṣùgbọ́n Àwòko mọ̀ pé bí olóko bá fi bá Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ lórí jíjà pìtìpìtì, pípa ni yóó kọ́kọ́ pa á ná, kí ó tóó yọ okùn lọ́rùn rẹ̀. Àwòko bá sáré lọ sọ fún Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ kí ó má jà pìtìpìtì mọ́:

                  Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ ṣe bí èyí tó ó sùnlọ, má jà mọ́!

                  Ṣe bí èyí tó o sùn lọ!

         Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ gbọ́. Ó sinmi jíjà. Ó ṣe bí èyí tó ti kú. Ó mọ̀ pé àìgbọ̀ràn òun àkọ́kọ́ ló kó bá òun.

         Nígbà tí olóko dé, tí ó bá Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ń rọ̀ diro diro, inú rẹ̀ dùn. Ó rò pé ó ti kú, ni Olóko tú okùn lọ́rùn Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ kí o le tún okùn dẹ. Ó fi Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ lelẹ̀ lórí ebè. Ẹnì kan kò sọ fún Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó fi fò lọ! Ó ya olóko lẹ́nu púpọ̀. Àwòko wá ń fi olókùn ṣe yẹ̀yẹ́. Ó ń sọ pé:

                  Olókùn yí sẹran nù!

                  Ìpàkọ́ ẹ̀ rógódó sẹran nù!

Ẹ ẹ̀ rí nǹkan! Ṣé ẹ ráyé lóde? Ṣé ẹ rí iṣẹ́ àwọn àgbà láwùjọ? Ṣé ẹ rí iṣẹ́ ẹ̀yin olóṣèlú? Ṣé ẹ rí iṣẹ́ ìjọba. Ṣé ẹ rí Àwòko, nígbà tí ó mọ̀ pé Ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ kì í gbọ́ràn, síbẹ̀, kò kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ó tiraka, ó sì yọ ọ́ nínú ewu. Àwọn iṣẹ́ tí a lè fi èdè àti ìtàn sísọ ṣe nìwọ̀nyẹn.

          Ǹjẹ́ ẹ tilẹ̀ mọ̀ pé èdè abínibí ni ọmọ tí a bí yóò kọ́kọ́ sọ bí ó bá ti ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ láìsí ẹni tí ó fi kọ́ ọ? Irú ọmọ bẹ́ẹ̀ yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ wá kọ́ èdè mìíràn tí wọ́n bá ń sọ láyìíká rẹ̀ bí ó ṣe ń dàgbà sí i. Ó ṣe ni láàánú pé làwùjọ òde-òní, èdè abínibí tó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún èdè mìíràn tí ènìyàn yóò gbọ́ kò ní gbòǹgbò tó fi múlẹ̀ nítorí kí ọmọ tó lóye èdè abínibí rẹ̀ dáadáa ni a ó ti máa fi èdè mìíràn kọ́ ọ nítorí ọ̀làjú tó gbòde kan. Irúfẹ́ ìgbésẹ̀ yìí sì túbọ̀ ń ṣe àkóbá fún lílóye èdè abínibí ni. Ìpalára ńlá ló sì tún ń ṣe fún ọmọ nítorí pé kò ní sí èyí tí yóò gbọ́ dáadáa nínú èdè abínibí àti èdè tó yẹ kó jẹ́ àkọ́kúntẹni. Pabanbarì rẹ̀ ni ìròyìn kan tí ìwé ìròyìn The Nation ọjọ́ kẹfà, oṣù kẹsàn-án ọdún 2012 gbé nípa àlàyé NERDC pé akitiyan láti dín iṣẹ́ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama ń ṣe nílé-ẹ̀kọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà kù ti ṣokùnfà kí ìjọba yọ àwọn èdè abínibí kúrò lára iṣẹ́ tó pọn dandan kí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe jáde nínú ìdánwò àṣekágbá oníwèé mẹ́wàá.  Ìpèníjà ńlá ni èyí jẹ́ fún gbogbo mùtúmùwà.

         Ọ̀kàn-ò-jọ̀kan ìgbésẹ̀ ṣì wà tí a lè láti ṣe àtúnṣe sí àṣìṣe wa nípa ìhà tí a kọ sí èdè abínibí. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kí á tún máa fetí sílẹ̀ sí ohun tí àjọ àwùjọ àgbáyé ń pàrọwà pé kí á máa ṣe kí àṣà wa má baà parun.

Ní ọdún 2004, UNESCO kéde láti gba àwọn àṣà kan wọ inú àwọn àṣà ti wọn ga jùlọ láyé, tí wọ́n jinlẹ̀ jùlọ, tí a kò rí irú rẹ̀ rí. Àwa fi IFÁ ránṣẹ́ sí UNESCO. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣà àgbáyé ni wọ́n jọ díje náà. Odidi ọdún kan ni UNESCO fi wo, ohun tí a kọ. Nígbà tí ó di ọdún 2005 èsì jáde, IFÁ sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí UNESCO mú. Wándé Abímbọ́lá ni a jọ ṣe iṣẹ́ náà àti Bádé Àjùwọ̀n. Ṣé ẹ mọ̀ pé Abímbọ́lá ni ó mọ̀ nípa IFÁjùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni Àwíṣẹ àgbáyé. UNESCO sì tún ṣe ètò kan tí wọ́n fẹ́ fi ṣe àgbéga àṣà ìbílẹ̀. Ohun tí wọ́n pè é ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ni “Living Human Treasures” to túmọ̀ sí “Àwọn Ìṣura Ìmọ̀ tí kò tí ì kú”. Àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ara tí ó dára jùlọ tí wọ́n sì wà ní ààyè.

         Àwọn ọmọ Yorùbá méjì ni a tún fi ránṣẹ́ sí UNESCO ní 2007. Àwọn ni Làmídì Fákẹ́yẹ, agbẹ́gilére tí gbogbo ayé mọ̀. Làmídì Fákẹ́yẹ ń ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì Ifẹ̀ nígbà náà. Ẹni kejì ni Ògúndáre Fọ́yánmu, gbajúmọ̀ oníjàálá ọmọ Ògbómọ̀ṣọ́. Ó ṣeni láàánú pé àwọn méjèèjì ti kú. Fákẹ́yẹ kú ní ìdunta, Fọ́yánmu sì kú léṣìí. Ṣùgbọ́n UNESCO kò kúrò níbẹ̀, kí a máa fetí sílẹ̀, kí á sì máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ní ká ṣe. Láìpẹ́ yìí ni a gbé Ìgbìmọ̀ Èdè ní Ilẹ̀ Áfíríkà (ACALAN) kalẹ̀ láti bójútó èdè abínibí. Ìpàdé Ìgbìmọ̀ yìí kan tó dá lórí èdè Yorùbá wáyé ní Cotonou, lórílẹ̀-èdè Benin ní lọ́ọ́lọ́ yìí. Inú ìpàdé náà ni àwọn onímọ̀ ti jíròrò nípa ìgbésẹ̀ tó yẹ ní gbígbé kí iná èdè Yorùbá lè máa jó geere. A wá rọ gbogbo wa pé kí a ṣe ohun tí ìgbìmọ̀ yìí bá ní kí èdè kọ̀ọ̀kan máa ṣe. Iṣu atẹnumọ́rọ̀ kì í jóná. Lára nǹkan tí ó yẹ kí a máa fi èdè Yorùbá ṣe ni fífi èdè yìí kọ́ àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ wa nílé láìfi èdè gẹ̀ẹ́sì kún-un. Ẹ jẹ́ kí a fi èdè gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ èdè àkọ́kúntẹni sílẹ̀ fún àwọn olùkọ́ tí yóò fi máa kọ́ àwọn ọmọ ní ilé-ẹ̀kọ́. Bákan náà ni à ń pe àwọn onísinimọ́ níjà kí wọ́n máa ṣe erémọdé kéékèèké ní èdè Yorùbá. Ìrètí wa ni pé irúfẹ́ àwọn erémọdé bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kí èdè Yorùbá túbọ̀ yé wọn, yóò sì tún jẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí èdè náà dáadáa. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni à ń pàrọwà sí àwọn adarí ètò lórí rédíò láti túbọ̀ máa ṣe ọ̀kan-ò-jọ̀kan ètò lédè Yorùbá nítorí àwọn ètò bẹ́ẹ̀ lè ṣí àwọn aráàlú létí láti túbọ̀ kọbiara sí èdè Yorùbá. Àsìkò sì tó wàyí fún àwọn ọba alayé wa gbogbo láti mú èdè Yorùbá lọ́kúnkúndùn lọ́nà tí àwọn ará ìlú yóò fi mọ̀ pé ó tọ̀nà láti gbé èdè àbínibí ẹni lárugẹ. Bí ọba alayé bá gba olórí ìlú lálejò tàbí bí àlejò òkèèrè bá yọjú sáàfin, èdè Yorùbá ló yẹ kí ọba sọ kí ògbufọ̀ kan máa túmọ̀ rẹ̀ fún àlejò. Ó sì tó àkókò kí ìjọba fi òté lé e pé ọ̀rànanyàn ni kí a máa fi èdè Yorùbá kọ́ ọmọ ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ bí èyí tí a ṣe ní St. Stephen, Modákẹ́kẹ́ ni ọdún mélòó sẹ́yìn. Ìjọba sì gbọ́dọ̀ tún òfin ṣe láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé dandan ni akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ ṣe èdè Yorùbá jáde ní ìdánwò àṣekágbá oníwèé mẹ́wàá. Kò sì léèwọ̀ bí àwọn aláṣẹ yunifásítì bá jẹ́ kí a fi èdè Yorùbá kọ ọmọ ní abala kan nínú ẹ̀kọ́ GST tí wọ́n ti ń kọ́ ọmọ nípa ìtàn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó sì yẹ kí Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà máa lo èdè Yorùbá lẹ́ẹ̀méjì dípò ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ kí àwọn ará ìlú lè ní àǹfàní láti lóye nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀; kì í ṣe àsìkò ìpolongo ìbò nìkan ló yẹ kí wọ́n mọ̀ pé èdè Yorùbá ló máa jẹ́ kí òye ohun tí wọ́n ń sọ yé ará ìlú. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ló yẹ kí àwọn aláṣẹ ìjọba ṣètò bí wọn ó ṣe máa yí àbọ̀ ìròyìn àti àbádòfin yòówù tó jade sí èdè Yorùbá kí gbogbo ènìyàn tó gbọ́ èdè náà lè rí i kà ní àkàyé. Lákòótán, ẹ jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa gbígbé èdè Yorùbá lárugẹ. Ire ò.

Lára nǹkan tí ó yẹ kí a máa fi èdè Yorùbá ṣe ni fífi èdè yìí kọ́ àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ wa nílé láìfi èdè gẹ̀ẹ́sì kún-un. Ẹ jẹ́ kí a fi èdè gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ èdè àkọ́kúntẹni sílẹ̀ fún àwọn olùkọ́ tí yóò fi máa kọ́ àwọn ọmọ ní ilé-ẹ̀kọ́. Bákan náà ni à ń pe àwọn onísinimọ́ níjà kí wọ́n máa ṣe erémọdé kéékèèké ní èdè Yorùbá. Ìrètí wa ni pé irúfẹ́ àwọn erémọdé bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kí èdè Yorùbá túbọ̀ yé wọn, yóò sì tún jẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí èdè náà dáadáa. Àsìkò sì tó wàyí fún àwọn ọba alayé wa gbogbo láti mú èdè Yorùbá lọ́kúnkúndùn lọ́nà tí àwọn ará ìlú yóò fi mọ̀ pé ó tọ̀nà láti gbé èdè àbínibí ẹni lárugẹ. Bí ọba alayé bá gba olórí ìlú lálejò tàbí bí àlejò òkèèrè bá yọjú sáàfin, èdè Yorùbá ló yẹ kí ọba sọ kí ògbufọ̀ kan máa túmọ̀ rẹ̀ fún àlejò. Ó sì tó àkókò kí ìjọba fi òté lé e pé ọ̀rànanyàn ni kí a máa fi èdè Yorùbá kọ́ ọmọ ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ bí èyí tí a ṣe ní St. Stephen, Modákẹ́kẹ́ ni ọdún mélòó sẹ́yìn. Ìjọba sì gbọ́dọ̀ tún òfin ṣe láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé dandan ni akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ ṣe èdè Yorùbá jáde ní ìdánwò àṣekágbá oníwèé mẹ́wàá. Kò sì léèwọ̀ bí àwọn aláṣẹ yunifásítì bá jẹ́ kí a fi èdè Yorùbá kọ ọmọ ní abala kan nínú ẹ̀kọ́ GST tí wọ́n ti ń kọ́ ọmọ nípa ìtàn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó sì yẹ kí Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà máa lo èdè Yorùbá lẹ́ẹ̀méjì dípò ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ kí àwọn ará ìlú lè ní àǹfàní láti lóye nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀; kì í ṣe àsìkò ìpolongo ìbò nìkan ló yẹ kí wọ́n mọ̀ pé èdè Yorùbá ló máa jẹ́ kí òye ohun tí wọ́n ń sọ yé ará ìlú. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ló yẹ kí àwọn aláṣẹ ìjọba ṣètò bí wọn ó ṣe máa yí àbọ̀ ìròyìn àti àbádòfin yòówù tó jade sí èdè Yorùbá kí gbogbo ènìyàn tó gbọ́ èdè náà lè rí i kà ní àkàyé. Lákòótán, ẹ jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa gbígbé èdè Yorùbá lárugẹ.

Gíwá, ẹ gbà mí láyè láti fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí ẹ̀yin aláṣẹ fásitì Adékúnlé Ajáṣin tó kà mí yẹ, tó sì tún gbà mí láyè láti ka ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí ní èdè Yorùbá. Oore ọ̀fẹ́ ńlá gbá à ni. Ẹ ṣeun, mo dúpẹ́ o. Mo tún lo àǹfàní yìí láti fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí àwọn ọ̀gá mi pàtàkì wọ̀nyí: Ọ̀jọ̀gbọ́n Àgbà Adébóyè Babalọlá tó ti sùn nínú Olúwa, Ọ̀jọ̀gbọ́n Àgbà Ayọ Bámgbóṣe àti Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọládélé Awobùlúyì; tí wọ́n ti fìgbà kan jẹ́ olùkọ́ mi lẹ́nu iṣẹ́ akáda. Mo tún lo àǹfàní yìí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Olúyẹ́mísí Adébọ̀wálé, Ọ̀mọ̀wé Dúró Adélékè àti Ọ̀mọ̀wé Àrìnpé Adéjùmọ̀ tí wọ́n jẹ́ olùbáṣiṣẹ́ mi nídìí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Yorùbá.

Ire ò.

ÌWÉ TÍ A YẸ̀WÒ

Adebọwale, O. 2011, Writing and Reacting: The Experience in Indigenous Yorùbá Literary Art. Akungba-Akoko: Adekunle Ajaṣin University.

Adefuyẹ, A. 1987, History of the Peoples of Lagos State. Lagos: Lantern

Books.

Awobuluyi, O. 2012, “Why We Should Develop Nigerian Languages”. A Keynote Address delivered at the 25th Annual Conference of the Linguistic Association of Nigeria held at Adekunle Ajaṣin University, Akungba-Akoko, Ondo State, Nigeria, 3rd -6th December 2012.

Fafunwa, A.B. 1989, Education in Mother Tongue. The Ife Primary Education

Research Project. Ibadan University Press Ltd.

UNESCO, 2002, Cultural Diversity Series No 1.

UNESCO, 2003, Convention for the Safeguarding of the Intangible Cultural

Heritage.

UNESCO, 2005, The Convention on the Protection and Promotion of the

Diversity of Cultural Expressions.

Ṣoyinka, in The Nation on Sunday, Jan. 2, 2011, p. 16.

Oguntọla in The Nation on Sunday, Oct 30, 2011, p. 23.

Olumhense in The Guardian Sunday Oct. 16, 2011,

About Author

Shoots Editor